Mínísítà fún Agbègbè Olú-ìlú Nàìjíríà (FCT), Nyesom Wike, ti ṣàpèjúwe ìdìbò tí agbègbè Olú-ìlú Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí “àlàáfíà” ó sì gbóríyìn fún àwọn olùdìbò fún ìwà àlàáfíà.
Mínísítà náà gbóríyìn fún wọn lẹ́yìn tó ṣe àkíyèsí ìdìbò náà ní Garki, Ààfin Olórí Karu, Karshi, Kabusa àti Keti.
Wike ṣàkíyèsí ìṣòro àìbìkítà àwọn olùdìbò, pàápàá jùlọ ní àárín ìlú, ó ní, síbẹ̀síbẹ̀, wí pé ìdìbò àwọn olùdìbò ní àwọn ìlú ìgbèríko jẹ́ òun ìyanu.

Mínísítà náà gbóríyìn fún àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò fún rírí i dájú pé wọ́n ṣe ìdìbò náà láìsí ìṣòro.

Nípa iṣẹ àwọn elétò ìdìbò náà, Mínísítà náà gbóríyìn fún Àjọ Elétò Olómìnira Ìdìbò Orílẹ̀-èdè, INEC fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe.
Comments are closed.