Take a fresh look at your lifestyle.

FCT pinnu : Ìdìbò bẹ̀rẹ̀ Ní Gbogbo ìlú Abuja.

42

Ìdìbò ti bẹ̀rẹ̀ ní Ẹ̀ka Ìdìbò 107, tí ó wà ní ojú ọ̀nà Parakakou, ní ìta Ahmadu Bello  ní Wuse 2, pẹ̀lú iye àwọn olùdìbò tí wọ́n ti dìbò díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkókò ìròyìn.

Nígbà tí ó ń bá aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP), Ọ̀gbẹ́ni Benjamin Tazan sọ̀rọ̀, ó fi àníyàn hàn lórí ìdúró tí àwọn ohun èlò ìdìbò ń dé, ó rọ àjọ (INEC) láti gba gbogbo ìdìbò ní pàtàkí.

Bákan náà, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní èdè Hausa, aṣojú All Progressives Congress (APC), Ọ̀gbẹ́ni Nuhu Jibrin, sọ wí pé ìdúró náà jẹ́ nítorí dídé àwọn ohun èlò ìdìbò díẹ̀.

Ní Kubwa 2, ìdìbò bẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù, ṣùgbọ́n ní agogo 9:30 òwúrọ̀, iye àwọn olùdìbò kò dára. Nínú 756 tí wọ́n forúkọ sílẹ̀, ènìyàn márùn-ún péré ló wà níbẹ̀ ní àkókò ìròyìn náà

Comments are closed.

button