Alaga àpapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Ọjọgbọn Nentawe Yilwatda ti sọ pé Osise ètò ìdìbò to pọ̀ wà lára okunfa oludibo to kéré jọjọ.
Èyí jẹyọ bakanna lati odò oludamọran pataki sì alaga apapo egbé oselu APC lori ọrọ ìròyìn àti ọgbọn atinuda ibaraẹnisọrọ, Abimbola Tooki.
Nigbati ó ń sọrọ nibi ìpàdé kan pẹlú àwọn alága ẹgbẹ oṣelu àti àjo INEC ní ilu Abuja, Ọjọgbọn Yilwatda jẹ kò sì mímọ pe, Osise àjọ INEC, eleto aabo, atọ̀pinpin ibo, eleto ilera, oniroyin àti àwọn kòṣeémáàní oṣiṣẹ yòókù eleto ìbò ní wọn pín kaakiri ti won kò ní ànfààní àti di ibo tiwọn ní ojó ibo didi.
O wà se ìkìlọ pé, ìbò ti wọn tete di ti wọn fipamọ di kika to ba yà
leè fa kí awon eniyan ma ni igbẹkẹle ninu wọn, o sì leè faye gbà mọ̀karuru ìbò.
Ọjọgbọn Amupitan tun sọ pé ìṣòro owó láti ṣe ètò ìdìbò kárí Nàìjíríà ní ojó kan wà níbẹ, pé yóò fẹ to ilọ́po méjì ohun eelo ti wọn nlo bayi láti lò nitori ibo ti kò bà asiko ti gbogbogbo mú a má fi àye silẹ láti tù ohun eelo ìdìbò lo lekan sì.
Ó kilọ̀ pe, ibo Olojo kan kaakiri orílẹ-èdè a máa fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àti ìṣòro lórí ohun eelo.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san