Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà, Palestine fìdí àjọṣepọ̀ wọn múl̀ẹ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

14

Mínísítà Nàìjíríà fún ọ̀rọ̀ òkèèrè, Aṣojú Yusuf Tuggar àti Aṣojú orílẹ̀-èdè Palestine sí Nàìjíríà, Muhannad Halmouri, ti gbà láti fì̀dí́ àjọṣepọ̀ ati ìfọwọ́wẹwọ́ aṣojú múl̀ẹ̀ láàrin orílẹ̀-èdè méjèèjì

Alaye kan ti agbẹnusọ fun ile iṣẹ ijọba apapọ ti n risi ọrọ okeere, Kimiebi Ebienfa, fi sita sọ pe, ipade naa waa lara iṣẹ ọlọgbọn ti n lọ lọwọ lati ṣe ifesẹrinlẹ ajọṣepọ to wa laarin Naijiria ati orilẹ ede Palestine, ti yoo si tun pese anfaani lati ṣagbeyẹwo lori iṣoju, iran ọmọniyan lọwọ, ati awọn ọrọ ẹkun to kan awọn mejeeji.

Lasiko ipade naa, Aṣoju Palestine jiṣe ikini Adari ijọba Palestine ti o si tun dupẹ lọwọ Naijiria fun aduroti ọlọjọ pipẹ ati iranlọwọ fun adawọle Palestine.

O wa ranti itan ajọṣepọ Naijiria ati Palestine, lati asiko Aarẹ Yasser Arafat, ati iṣe daadaa Naijiria nigbogbo igba ati ajọṣepọ ọlọgbọn kariaye.

Wọn ṣapero lori ipo iran awọn ọmọ niyan lọwọ ni Gaza ati awọn agbegbe Palestine to lọ siwaju.

Asoju naa ba Minisita Naijiria ti n ri si ọrọ okeere sọrọ lori nkan ti n lọ lọwọ, ti o fi mọ ipeninija ailaabo to n lọ lọwọ ati ipeninija lori  ailaafaani si iran ọmọ niyan lọwọ, ti o si ni ohun mọ ipa ribiribi Naijiria ati iyanju atilẹyin lati yanju rogbodiyan naa pẹlu irọrun, ofin kariaye ati boṣe tọ bo ṣe yẹ.

Comments are closed.

button