Gbajúmọ̀ akọrin ìgbàgbọ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, adari ìyìn àti olùṣọ àgùntàn, Ron Kenoly ti papòdà ní ẹni Ọ̀kànlélọ́gọ̀rin Ọdún.
Iku rè ní wọn sọ pé o wáyé ní ojó keta oṣù keji ọdún 2026, ti gbogbo ènìyàn paapaa julọ láti ìdílè onigbagbọ kaakiri aye ti n fi aidunnu wọn han nípa ikú akọrin Ìgbàgbọ́ náà àti sì àwọn mọlẹbi rẹ.
Wọn bíi ní ọjó kefa oṣù Kejìlá ọdún 1944. Lára awọn orin to kọ to gbèè jade láti ri:
Lift Him Up ní ọdún 1992, “Ancient of Days,” “Jesus Is Alive,” “We’re Going Up,”ati God Is Able, Welcome Home. abbl. ti ọpọ ìjọ kárí aye a si máa kọ.
Akọrin Ìgbàgbọ́ orílẹ-èdè yìí Nathaniel Bassey àti gbajumọ orin iyin lógò míràn gbosuba fún iṣé ribiribi ti ogbontagi
Olorin ẹ̀mí náà ṣe kolojo to de.
Òhun tó fà sababi iku rẹ̀ ní wọn kò tíì sọ fáráyé gbọ láti ọdọ ìdílé rẹ. Ètò ìsìnkú rẹ ní ìgbàgbọ wà pẹ wọn yóò kéde rẹ laipẹ́.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san