Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀fíìsì Ààrẹ Gbósùbà Ràbàndẹ̀ Fún Ìpínlẹ̀ Èkó

22

 

Ọ̀fíìsì ààrẹ ti gboriyin fún ipinlẹ Èkó latari pe wọn kéde rẹ̀ pé o jẹ ọkan ninu ipinlẹ to yara dàgbà julọ lagbaye nibi ti imọ ẹrọ to súyọ, wọn jẹri sì pé, ìdàgbàsókè ọtun yìí fihan pé ijọba ààrẹ Tinubu ń ṣe bẹbẹ tẹ̀gàn kọ́.

 

Nígbà ti o sọrọ nipa igbewọ̀n yìí lórí ẹrọ ayélujára “X” rẹ, oludamọran pataki lórí oro irohin àti ọgbọn atinuda, ọgbẹni Bayo Onanuga sọ pé aseyege yìí fihan pé ijọba yìí n ṣe aseyori nipa ọrọ ajé.

 

Bí wọn se tẹ̀wọ̀n sì, ìlú Èkó lo lewaju Istanbul ní Turkey, Pune ní India, Belo Horizonte ní Brazil, Mumbai ní India, àti àwọn ìlú nlá ni Kọ́ńtínẹ́ntì Asia, Africa ati South America pátápátá.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button