Bo tilẹ jẹ pe atamatase ikọ Chelsea, Romelu Lukakau ko si lori papa, wọn ko gbẹyin rara pẹlu bi wọn se fakọ yọ ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ Liverpool.
Sadio Mane lo kọkọ gba bọọlu wọle fun ikọ Liverpool, ti Mohammed Salah si gba ẹlẹẹkẹji wọle. Leyi ba ru ikọ Chelsea ninu, ni Mateo Kovavic si da ọkan pada. Laipe jọjọ naa ni Christian Pulisic da ẹlẹẹkẹji pada.
Ikọ mejeeji lo gbiyanju lati mori bọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, sugbon aparo kan ko ju ọkan lọ laarin ikọ mejeeji. Ọmi ni ifẹsẹwọnsẹ naa pari si.
Leave a Reply