Ìmọ̀ Àtọwọ́dá (AI) Lè Rọ́pò Oníròyìn Tó Bá Kọ̀ Láti Ní Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Díjítà Òde Òní – Alága Ẹgbẹ́ Oníròyìn
Alága àgbáríjọ ẹgbẹ́ oníròyìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, NUJ, Akeem Babatunde Abas ti sọ di mímọ̀ pé ọgbọ́n àtọwọ́dá ti a mọ̀ sí Artificial Intelligence (AI) lè rọ́pò àwọn oníròyìn tí ò bá kọ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ díjítà ode òní.
Abas ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ méjì lórí ìmọ̀ ọgbọ́n àtọwọ́dá fún ọgọ́fà (120) oníròyìn jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ méjì náà ni ẹgbẹ́ oníròyìn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ìdarí Alága rẹ̀ Akeem Abas ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ pẹlu àjọṣepọ̀ American Open University, Nigeria, láti ró àwọn oníròyìn lágbára nípa bí a ṣe n lo ìmọ̀ ọgbọ́n àtọwọ́dá (AI) fún irọrun ìtànkálẹ̀ ìròyìn.
Alága NUJ, ẹni tó ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀ pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe pàtàkì fún ìkọ́ni àti ìrónilágbára, jẹ́ kó yé àwọn olùkópa pé bí Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń tẹ̀ sí ipa ọ̀nà ètò ìṣúná tí ó dá lórí ìmọ̀, o ṣe pàtàkì kí àwọn oníròyìn náà ni àfojúsùn fún ìyípadà. Nítorí náà, ó gba gbogbo àwọn olùkópa nímọ̀ràn láti ní ojú ìwòye fún ṣíṣe ìwàjinlẹ̀ ìròyìn àti ìròyìn eléyìí tó n wá ojútùú sí ìṣòro yatọ sí iroyin to lè mú dàrúdàpọ̀ wá.
Bákan náà, Alága ẹgbẹ́ oníròyìn fi àsìkò náà ké sí àwọn oníròyìn láti ri dájú pé wọ́n ṣe àyẹ̀wò ìròyìn dáadáa, kí wọ́n sì tan ìmọ̀lẹ̀ sí aráàlú lójúnà àti ró ìjọba àwa-ará-wa lágbára.
Nígbà tó gba gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn láti rí ríró oníròyìn lágbára gẹ́gẹ́ bíi ìdókòwò ìṣèjọba eléyìí tí yóò rẹ́sẹ̀ walẹ̀, Ó ṣàlàyé pé ọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ àtọwọ́dá (Artificial Intelligence) gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun èlò tí yóò gbé ìṣèjọba àwa-ará-wa lárugẹ, kii ṣe èyí ti yóò dá kún ìṣòro rẹ̀.
Nígbà tó n síde ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ méjì náà, ẹni tii ṣe Kọmíṣọ́nnà fún ìròyìn ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọmọ-ọba Dọtun Oyelade ṣàlàyé pé ọgbọ́n ìmọ̀ àtọwọ́dá (AI) jẹ ògúnná gbòngbò ohun èlò iṣẹ́ ìròyìn gẹgẹ bí o ṣe wa lóde òní ati bí yóò ṣe wà lọ́jọ́ iwájú.
Kọmíṣọ́nnà wá gba àwọn akọ̀ròyìn to kópa láti lo anfààní ọgbọ̀n tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà kọ́ wọn fún ìwúlò ara wọn àti àwùjọ lápapọ̀.
Ẹni tii ṣe Alákóso Ilé-ẹ̀kọ́ Gíga American Open University ní Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n David Akanbi nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé “Lílò Ìmọ Àtọwọ́dá, AI láti ró àwọn Oníròyìn lágbára Fún Ìròyìn ìwà-ọmọlúàbí, ìmó ọtun, fún ọjọ́ iwájú iṣẹ́ ìròyìn.” ṣàpèjúwe ohun mẹ́ta pàtàkì tó jẹ́ ìpèníjà fún iṣẹ́ oníròyìn gẹ́gẹ́ bí ìtànkálẹ̀ ìròyìn àìtọ́ (misinformation), ìtànkálẹ̀ ìròyìn láti tan ènìyàn jẹ (disinformation), àti ìpolongo ìròyìn èké (propaganda).
Nítorí náà, ó rọ̀ àwọn oníròyìn láti lo Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Ọgbọ́n Àtọwọ́dá (AI) gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ fún ìgbéláruge iṣẹ́ ìròyìn .
Abiola Olowe
Ìbàdàn.