Àjọ National Sports Commission (NSC), ti sọ àsọdajú pe àwọn eléré ìdárayá Nàìjíríà yóò peju pésẹ̀ nibi igbaradi ọlọ́sẹ̀ mẹ́rin ni orílẹ̀-èdè Scotland latàri Ìdíje Kọ́mọ́wẹ́ẹ̀tì ọdún 2026 to n bọ̀.
Ọgá agba àjọ NSC, Bukola Olopade, ló sọ èyí di mímọ̀ ninu àkọsílẹ láti ọdọ Dokita Kehinde Ajayi to jẹ Olùdarí ètò iroyin àjọ NSC.
Ọ̀gbẹ́ni Olopade sọ pé, igbaradi ti yóò wáyé ní ilu Aberdeen orílẹ-èdè Scotland yóò wúlò fún ètò ìṣàkóso àti pé yóò dín wàhálà Ìrìn-àjò kù fún ikọ̀ ti Nàìjíríà.
Ìdíje Kọ́mọ́wẹ́ẹ̀tì ọdún 2026 yóò wáyé ní ilu Glasgow, Scotland, bẹ̀rẹ̀ láti ojo kẹtàlélógún oṣù keje sì ọjọ Kejì oṣù kẹjọ ọdún 2026 nibi ti wọn yóò ti ma ṣe ere ìdárayá mẹwàá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san