Ọ̀gá àgbà fún àwọn ọmọ ogun, ajagun Faruk Yahaya (COAS), sọ pé òhun nírètí pẹ̀lú àìtúrasílẹ̀ àti ìgboyà àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè (NACA) àti ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ìdánilékọ̀ọ́ àwọn ologun, (NATRAC) lórí akitiyan wọn láti gbógun ti àwon adigunjalè àti lààsígbò ààbò wọn ní Kontagora àti Ìpínlẹ̀ Niger lápapọ̀.
COAS sọ eyi di mimọ lakoko ti o n ba awọn ọmọ ogun ikọ mejeeji sọrọ lakoko abẹwo iṣẹ akọkọ rẹ si Nagwamatse Barracks, Kontagora, Ipinlẹ Niger ni ọjọ kejila, Oṣu kejila ọdun 2021.

O sọ pe inu ohun dun pẹlu bi awọn ọmọ ogun ṣe fakọ yọ, o wa rọ wọn lati ma je ko rẹ lati maa ba iṣẹ ribiribi wọn lọ.Otun wa sọ pe ,igbe aye alaafia wọn ati ti ẹbi wọn jẹ ohun logun pupọ fun idi eyi ko si si nnkankan ti yoo yi pada.
Leave a Reply