Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ Shettima Tí Gbéra L’Abuja Fún Ìfilọ́lẹ̀ Ààrẹ Guinea-Conakry

120

Ìgbákejì Ààrẹ Kashim Shettima tí gbéra ní Abuja láti ṣojú Ààrẹ Bola Tinubu níbi ìfilọ́lẹ̀ Ààrẹ Mamadi Doumbouya tí Guinea-Conakry.

‎ Ó tún ṣètò láti lọ sí Ìpàdé Ọlọdọọdún tí Ìgbìmọ̀ Ìṣòwò Àgbáyé (World Economic Forum WEF) tí ọdún kẹrindinlọgọta ní Davos, Switzerland, lẹ́yìn tí ó kópa nínú ìfilọ́lẹ̀ Ààrẹ ní orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà.


‎Igbákejì Ààrẹ yóò ṣojú fún Ààrẹ Tinubu níbi ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ Ààrẹ Doumbouya, lẹ́yìn tó jáwé olúborí nínú ìdìbò rẹ̀. A ṣètò ayẹyẹ náà láti wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kìíní, ní Pápá Ìṣeré GLC, Nongo, Conakry.

Comments are closed.

button