Àjọ NDYC, ní Ọjọ́rún ti bèèrè fún àtìlẹyìn ìjọba àti àwọn ti ọ̀rọ̀ kàn láti gbógunti ìtànkálẹ̀ àrùn ọpọlọ ní àgbègbè náà
Ọ̀gbẹ́ni Jator Abido, tí ó jẹ́ alákòso àpapọ̀ fún àjọ NDYC ni ó pe ìpè náà níbi eré ìtagbangba tí ó wáyé ní ilé ìwé gíga Yunifásitì ti ìlú Port Harcourt, èyí tí ó ń pèpè fún àmójútó àti ìdènà fún àrùn ọpọlọ
Abido sàlàyé pé ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà wáyé pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin Yunufásitì ti Port Harcourt, Àjọ NDDC, Àjọ Cradle ati NDYC. Ó sàpèjúwe ìgbésẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wáyé ní àsìkò tí ó sì se pàtàkì, èyí tí yóò ta àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ jí láti gbógunti àìsàn àrùn ọpọlọ ní àgbègbè náà