Ààrẹ Tinubu ti ki Lucky Orimisan Aiyedatiwa kú oriire bi wọ́n ti ṣe se ìbúra fún si ipò Gómìnà tuntun ìpínlẹ̀ Ondo pé kó tẹ̀lé àwòkọ́ṣe rere asíwájú rẹ̀.
Ààrẹ gba Aiyedatiwa nímọ̀ràn kí ó lo ijọba rẹ̀ láti sìn àwọn ènìyàn rẹ̀, kí ó lé ìṣẹ́ lùgbẹ́ tèfètèfè, kí ó tẹ̀lé àwòkọ́ṣe rere tí olóògbé Rotimi
Rotimi Akeredolu, kí ó ri pé ìlú tẹ̀síwájú kí ó gòkè àgbà.
Ààrẹ Tinubu rọ̀ọ́ wípé kí ó se nǹkan rere tí àwọn ènìyàn fẹ́ fún ìtèsíwájú ìpínlẹ̀ Ondo àti Nàìjíríà lápapọ̀.
Gómìnà Aiyedatiwa ni wọ́n se ìbúra fún ní ọjó ajé ní ìlú Akure tí ṣe Olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san