Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu gbàlejò Super Eagles

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

212

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ́lù Super Eagles ti bá Ààrẹ Bọla Tinubu lálejò ní ilé ìgbìmọ̀, ní ilé orílẹ̀-èdè, ní Abuja.

O n gbalejo wọn lẹyin ikopa wọn ninu ipele ikẹyin ninu idije ife awọn orilẹ ede Adulawọ  (AFCON) 2024, ti o waye ni Côte d’Ivoire

Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa ati oṣiṣẹ lo wa nijoko nibẹ afi Alex Iwobi ti o koju  cyber-attacks  nigba ti Cote D’Ivoire ja Naijiria danu ni ipele ikẹyin ninu idije ife awọn orilẹ-ede Adulawọ ti o ṣẹṣẹ pari yii.

A o ranti pe aarẹ  Tinubu ti sọ ninu alaye kan ti o fi sita nipasẹ oludamọran pataki rẹ lori eto ibaraẹnisọrọ ati ipolongo, Ajuri Ngelale, ti o gboriyin fun ẹgbẹ naa, ati gbogbo awọn oluṣakoso ẹgbẹ naa fun iṣẹ ti wọn ṣe ninu ifigagbaga naa.

Aarẹ tun wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati jẹ oniwuri, ti o si ṣalaye pe a gbiyanju fun Adulawọ, ti a si dara lagbaye, a fi agbara, ati ifọkansi han lori papa iṣere.

Comments are closed.

button