Take a fresh look at your lifestyle.

Burna Boy, Tems Wa Lára Àwọn Ọgọ̀rún Olórin Tó Dára Jùlọ Bí New African Magazine Se Gbekalẹ̀

262

 

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló wa ní ipò òkè bi New African Magazine se gbèe ogorun oruko awon olórin tó lààmì laaka ni ilẹ̀ Adulawọ ti ọdún 2023 jáde.

Ìwé ìròyìn náà gbé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn jáde lati eka bíi oselu, ilé iṣẹ, ìgbayì-láwùjọ, ogbon atinuda, sayensi, ẹkọ, ere idaraya abbl.

Àwọn ti wọ́n mọ̀ jù láàárín wọn nínú àtẹ náà ni Olorin ọmọ Naijiria, Tems ati Burna ti won ti gba àmì ẹyẹ Grammy ri, ti awọn eniyan mo pelu awon ogbontarigi Olorin bii: DJ Black Coffee ti orile-ede South African, Pop star Tyla, disc jockey DJ Snake ti ile Algeria àti The 3Weeknd ti won bi ni Ethiopia, megastar ti ilẹ̀ Canada. Fífi àwọn Olórin wọ̀nyí sí ṣe afihan iwulo wọn ni agbaye.

Iwe iroyin New African je iwe iroyin oyinbo osoosu ti o fi ilu London se ibujoko, o ti bere lati odun 1966. Won n kàá kaakiri ile Adulawo, o ti pẹ́ jọjọ, o sí n ta warawara ju akẹgbẹ rẹ lọ ni ilẹ̀ Adúláwọ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button