Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjàmbá Ọkọ̀ Ogun Òfurufú Pa Ènìyàn Méjì

201

 

Ọkọ̀ Ogun Ofurufu fi orí sọ ilé ìgbé ni agbègbè ìwọ̀ oòrùn Ntoroko, orílẹ̀-èdè Uganda, ó sì polúkúmusu.

Iṣẹlẹ náà wáyé ni àlà pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ orílẹ̀-èdè olominira Congo to sì pa gbogbo awọn eniyan to wa ninu rẹ àti ènìyàn to wa nínú ilé to forísọ bi ọ̀gágun
Felix Kulayigye- agbẹnusọ àwọn ológun Uganda se sọ.

Iṣẹlẹ buruku ojiji náà ti sọ àwọn olùgbé ileto náà sinu ẹ̀rù àti ìbànújẹ́, wọ́n sì fẹ kí ìjọba gbe igbesẹ̀ to yẹ ní wàrànsesà.

Àwọn ọmọ ologun orílẹ̀-èdè Uganda tilẹ̀ ti n sọ Àdó oloro sí àwọn ọ̀tá wọn esinòkọkú-Allied Democratic Forces (ADF) ti ìròyìn roo pé àwọn ọta náà ti n se ọpọlọpọ ìkọ̀lù sí Ntoroko.

Ààrẹ Yoweri Museveni ti pè fún àwọn ènìyàn tí kò ti di ológun tán láti darapọ̀ mọ́ àwọn ológun gidi láti dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button