Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Fẹ́ Ki Wọ́n Fi Òùntẹ̀ Lu Ìgbasísẹ́ Adájọ́ Tuntun Mọ́kànlá Sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jùlọ Nàìjíríà

205

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ń fẹ́ ki àwọn Sẹ́nètì bù ọwọ lù ìgbàsisẹ adájọ́ tuntun Mọ́kànlá si Ilé ẹjọ́ gíga jùlọ Nàìjíríà tó fi ṣọwọ́ sí wọn.

Ìbéèrè ààrẹ wa ni ibamu pẹ̀lú lẹ́tà tó ko sí ààrẹ ile igbimọ aṣòfin, Godswill Akpabio ti won sì ti ka sí etí ìgbìmọ̀ ni ọjọ Ojoru

Àjọ National Judicial Council (NJC) ti adájọ àgbà orílẹ̀-èdè yi ń dari ló yan àwọn mọ́kànlá náà tó sì fi sowo sí aare
Tinubu. Wọ́n nilati buwọ́lu wọn ki wọn tó se ìbúra fún wọn gẹ́gẹ́ bi adájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jù.

Àwọn adájọ́ ti wọ́n yàn niyi:

Haruna Simon Tsammani (Ariwa-ila oorun); Moore Aseimo Adumein (Gusu-gusu), Jummai Hannatu Sankey (North-central), Chidiebere Nwaoma Uwa (Gusu ila oorun), ati Chioma Nwosu-Iheme Gusu ila oorun.
Obande Festus Ogbuinya (Gusu ila oorun), Stephen Jonah Adah (Aarin gbùngbùn Ariwa), Habeeb Adewale Abiru (Gusu iwo oorun), Jamilu Yammama Tukur (Ariwa-iwo oorun), Abubakar Sadiq Umar (Ariwa-iwo oorun), ati Mohammed Baba Idris (Aarin gbùngbùn Ariwa).

Adájọ́ àgbà tó wà lórí àléèfà, Olukayode Ariwoola, ti jẹ̀jẹ́ pé, ó pan dandan ki òun ri dájú pé oye adájọ́ tó yẹ kó wà ló wà nílé ẹjọ́.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button