Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà Tún Ṣé Àfihàn Ìgbìyànjú Rẹ̀ Sí Ẹbí Àwọn Akínkanjú Tó Kú Lójú Ọnà Àlàáfíà Nàìjíríà

0 248

Ìgbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Kashim Shettima, tí tún ṣé àfihàn tí ìṣàkóso Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti ṣé ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn ọmọ-ogun Nàìjíríà, pẹ̀lú àwọn ìdílé tó pàdánù ẹmí àwọn ọmọ wọ́n lójúnà wá àlàáfíà sí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

O sọ pé ìpinnu ìṣàkóso náà ní láti ṣé àfihàn àwọn akínkanjú wọnyí ní ìbámu pẹ̀lú iṣọkan Nàìjíríà àti ìpèsè àlàáfíà ní Àgbáyé.

Tún kà nípa:Mínísítà Yan Kọmití Asètò Fún Ọjọ́ Ìrántí Àwọn Ológun

Ìgbákejì Ààrẹ tó sọ èyí ní kété lẹyìn tí wọ́n ṣé lọ́ṣọ́ pẹ̀lú ààmì ọjọ́ ìrántí àwọn akínkanjú tí ọdún yìí, (2024 Armed Forces Remembrance Day) ní ilé-iṣẹ́ Ààrẹ ní Abuja.

O tún rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà látí máa rántí àwọn ìdílé àwọn akínkanjú tó ṣubú ní ìgbàgbogbo, pàápàá nípa fífún wọ́n ní òun èlò nípasẹ Ẹgbẹ́ ọmọ ogún Nàìjíríà fún àlàáfíà àwọn ololufẹ wọ́n.

Tí á bá rántí pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí ṣé ìfilọ́lẹ̀ Ìgbìyànjú fún Ọjọ́ Ìrántí Àwọn ológun tí ọdún 2024 ní Oṣù Kẹwàá, Ó sí tún ṣé ìpinnu ìjọba rẹ̀ láti tún àwọn ilé-iṣẹ́ ológun ṣé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button