Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Niger fa ojú àwọn olùdókòwò mọ́ra ní Saudi

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 150

Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, Umar Mohammed Bago ti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ Ma’ad ní Jeddah, Saudi Arabia, láti fa àwọn ìdókòwò wá sí ìpínlẹ̀ náà, pàápàá fún iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ohun Àlùmọ̀ọ́nì inú ilẹ̀. Eléyìí jẹ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ nínú ìtàn ìpínlẹ̀ Niger.

Gomina Bago, ti o fi idi ẹ mulẹ pe ipade naa so eso rere, tun wa sọ pe idi ajọṣepọ pẹlu orilẹ-ede miiran ni lati mu ipinlẹ Niger di ipinlẹ to ni idokowo oriṣiriṣi, ki osi le figa gbaga pẹlu awọn orilẹ-ede kariaye.

Image

Image

Laipẹ yii, Gomina Bago kopa ninu agbekalẹ idagbasoke amayedẹrun to n lọ lọwọ bayii, ni Saudi Arabia, ti awọn oludokowo si ṣetan lati ṣe iranlọwọ fun ọpọlọpọ idokowo lori iṣẹ ọgbin ati iṣẹ akanṣe didaa ọna si meji ni ipinlẹ Minna ati Bida.

Ipade naa ti o waye ni Mecca, Saudi Arabia, jẹ idunadura iṣiwaju lori ohun elo inawo amayedẹrun ti o to ọpọlọpọ Biliọnu Dọla lati ile ifowopamọ idagbasoke Musulumiis (IsDB) lati kowo le iṣe akanṣe ni orisiriṣi abala amayedẹrun ni ipele ijọba apapọ ati awọn agbegbe ninu orile-ede ni Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button