Take a fresh look at your lifestyle.

COAS ṣe àgbékalẹ̀ àwọn iṣẹ́ Àkànṣe ètò ẹ̀kọ́ ni àwọn agbègbè tí wọn ń gbé

Eyitayọ Fauziat Oyettunji

0 211

Ọ̀gá Àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ológun (COAS), Ajagun Taoreed Lagbaja ti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn yàrá ìkàwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ túnṣe,tí gbogbo nǹkan sì pé síbẹ̀, kànga àti ilé-ìgbọ̀nsẹ̀, ní ilé ìwé alákọ̀́bẹ̀rẹ̀ Mbiabong Etim, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ini  ti Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.

Eleyii wa lara Agbekalẹ  Iṣẹ Akanṣe  Pataki ifọwọsowọpọ ara ilu-ologun ti Ọ̀gá Àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ológun (CSICP), ni iyẹsi Ajagun Udoh Bassey ti o jẹ ọmọ bibi agbegbe naa.

Ajagun Lagbaja sọ pe iṣẹ akanṣe yoo tunbọ mu eto ẹkọ lọ geere fun awọn olujanfaani ni agbegbe naa.

COAS sọ pe wọn da (CSICP) silẹ lati pese iranlọwọ fun awọn agbegbe ti awọn agba oṣiṣẹ ologun Naijiria (NA) jakejado orilẹ-ede ti wọn ti ni agbega si ipo Ọga Agba Gbogbogboo NA, nipasẹ iṣẹ ati ifarasin n gbe.

O wa sọ pe iṣẹ Akanṣe naa yoo kun awọn ohun elo to ti wa nilẹ tẹlẹ, ohun Amuludun, ati Amayedẹrun ti ipinlẹ ti pese fun awọn agbegbe naa tẹlẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button