Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu ṣàjọyọ̀ ọjọ́ ìbí ọdún karùnlè-lọ́gọ́rin Akọ̀wé ìjọba ẹlẹ́ẹ̀kejì, Baṣọrun

Eyitayó Fauziat Oyetunji

0 188

Ààrẹ Bọla Tinubu ti ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú ẹni ọ̀wọ̀, Baba Aladura Reuben Ọlọrunfunmi Baṣọrun, ẹni tí ó fi ìgbà kan jẹ́ Akọ̀wé ìjọba ẹlẹ́ẹ̀kejì fún ìjọba ìpínlẹ̀ Eko, bí ó ṣe ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún karùnlè-lọ́gọ́rin rẹ̀.

Ifiranṣẹ aarẹ naa wa ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale buwọlu.

Aarẹ wa fi ọpẹ fun ọlọrun fun ibukun ati aanu rẹ lori eniyan pataki yi, ti o ti ṣe aṣeyege lori ojuṣe rẹ gẹgẹ bii Agba ilu, Oloṣelu, Oṣiṣẹ ile ifowopamọ tẹlẹ ri, adari ẹgbẹ, Agbẹjọro, Ojiṣẹ oluwa, ati Asiwaju ti Igbogbo ni agbegbe Ikorodu, ni ipinlẹ Eko, ti eyi si mu ki o fi ipa ifarada lelẹ ni idi iṣẹ ati ijiṣẹ rẹ.

Aarẹ Tinubu ranti amojuto finifini Baba Aladura, ifọkansi awọn ojuṣe, ifaraṣe, ikunju osunwọn ti ko lafiwe ati ọpọlọpọ imọ adari pẹlu iṣe to wuni lori, ifarasin ati iṣe to ta wọn yọ lasiko ojuṣe pataki rẹ lori ijọba Oloogbe Alhaji Lateef Jakande.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button