Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbìmọ̀ Aṣojú pinnu láti ṣètò ìgbanisíṣẹ́ àpapọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 218

Ìgbìmọ̀ Aṣojú lórí ètò ìgbanisíṣẹ́ àpapọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè, ti pinnu láti ríi pé gbogbo ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ ni yóò jàǹfààní ìgbanisíṣẹ́ ní àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba, láti ṣe àfihàn  ìgbanisíṣẹ́ àpapọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè àti láti ṣàgbélárugẹ ìsọ̀kan orílẹ̀-èdè.

Alaga igbimọ naa, Asoju Idris Wase, ṣe amudani loju yii nibi ifilọlẹ igbimọ naa ni Abuja. O tun wa sọ pe igbimọ naa yoo ṣe amojuto rẹ finifini lati ri pe wọn pin igbanisiṣẹ naa ni ọgbọọgba jakejado orile-ede.

Aṣoju Wase tun ṣalaye pe igbimọ naa ni atilẹyin Aṣofin lati ṣe ojuṣe pataki naa. O paṣe pe ki igbimọ  ìgbanisíṣẹ́ àpapọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè (FCC) yọju si ile igbimọ lọse to n bọ ni ọjọ Iṣẹgun lati ṣalaye bi wọn yoo ṣe ṣe atẹwọgba pipin igbanisiṣẹ kaakiri orilẹ-ede lọgbọọgba.

O wa gba awón ómó égbé igbimó naa nimóran pe ki wón o ni ifé Naijiria lókan lasiko ti wón ba n ṣiṣẹ wọn.

Wọn yan awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ naa ni awọn ipinlẹ mẹrindin-logoji orilẹ-ede.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button