Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà ṣetán láti ṣe àpèjọ ààbò oúnjẹ alákọ̀ọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 188

Ìjọba Nàìjíríà ti ṣetán láti ṣagbatẹru alákọ̀ọ́kọ́ àpèjọ ètò Ọ̀gbìn lápapọ̀ àti ààbò oúnjẹ lórílẹ̀-èdè fún ìgbé ayé àlàáfíà àwọn àgbẹ̀, pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ àti láti yanjú àwọn ìpeniníjà tí ń kojú abala oúnjẹ Nàìjíríà.

Minisita fun eto ọgbin ati aabo ounjẹ ní Naijiria, Abubakar Kyari sọ eleyi di mimọ ni Abuja, olu orile-ede Naijiria nigba ti o n gbimọ ilana fun abala eto ọgbin ni ọdun mẹrin si asiko yii.

Gẹgẹ bi Kyari ṣe sọ, àpèjọ eto Ọgbin lapaapọ ati ààbò oúnjẹ yii “yoo mu gbogbo awọn to nii ṣe gbimọ pọ fun idagbasoke Ipinnu Iṣe lapapọ fun aabo ounjẹ pẹlu ọgbọn imuṣe ati ibiafẹede.”

O wa sọ pe apejọ naa tun wa fun lati jumọ ṣe pọ pẹlu awọn to ni ifẹ ati atilẹyin awọn to ṣe pataki ninu eto ọgbin Naijiria, lati kọju mọ aabo ounjẹ, ounjẹ ti owo rẹ ko jara lọ ti ko si tun lewu, ati igbe alaafia awọn agbẹ.

Apejọ naa yoo waye ni oṣu Belu 2023, ti aarẹ Ahmed Bola Tinubu, GCFR yoo si ṣe alaga ati iṣiṣọ loju rẹ, yoo si tun ṣe awọn ikede pataki kan ati itaniji fun awọn to nii ṣe pẹlu iṣẹ ọgbin.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button