Ìjọba Ìpínlẹ̀ Edo yóò ṣe ètò àti ra àwọn ọkọ̀ elérò (CNG-Buses) fún ìrọ̀rùn lílọ bíbọ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki ti sọ pé òun ti fẹ́ ra àwọn ọkọ̀ elérò (CNG) tuntun tí yóò kún àwọn tó ti wà tẹ́lẹ̀ fún ìrọ̀rùn lílọ bíbọ̀.Wọ́n ń ṣe eléyìí nítorí bí ìjọba àpapọ̀ ṣe yọ àdínkù owó epo ilẹ̀. Gómìnà sọ èyí nínú ọ̀rọ̀ àyájọ́ òmìnira rẹ̀.
O wa sọ pe inu oun dun fun ipa agbekalẹ naa, leyi ti o de ọna ilu-si-ilu mẹtala ati ọna arin ilu lọpọlọpọ, ti o si de awọn igberiko ati abule laarin ijọba agbegbe mẹta ipinlẹ naa.
O sọ pe awọn olugbe ti o ju ọọdunrun egbẹrun lọ lo ti janfaani eto idẹrun naa ni ọsẹ meji alakọọkọ, ti awọn olugbe ti o le ni miliọnu kan yoo si janfaani eto gbigbe lọ bọ fun oṣu meji alakọọkọ naa lọfẹẹ.
“A tun ti fẹ ko awọn ọkọ elero CNG miiran si lati mu rọrun ba awọn olugbe,” he noted.
Gomina tun sọrọ lori awọn igbesẹ miiran ti o ti gbe lati din inira ipa owo gọbọhi ati lọ bọ.
Leave a Reply