Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Ukraine Balẹ̀ Gùdẹ̀ Sí Canada

0 197

 

Ààrẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ti dé sí Canada. Ẹ̀rọ Mọ́hùnmáwòrán ti ilẹ̀ Canada se àfihàn ààrẹ Justin Trudeau tó ń pàdé ọ̀gbẹ́ni Zelensky àti obinrin àkọ́kọ́ ni pápákọ̀ òfúrufú ni ìlú Ottawa.

Ààrẹ Zelensky àti Obìnrin àkọ́kọ́, Olena Zelenska ni wọ́n ki káàbọ̀ nígbà ti wọ́n dé nípa dídì mọ́ra tàbí ìfàyà kàyà láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Canada ti ọ̀gbẹ́ni Trudeau ṣáájú wọn.

Orílẹ̀-èdè Canada ṣọ pé ó di dandan láti máa tẹ síwájú nínú ìrànwọ́ wọn sì ilẹ̀ Ukraine, Aṣojú Àjọ àgbáyé sọ pé, ó yẹ kí wọ́n tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.
A o se gbogbo nǹkan tó yẹ ká ṣe láti ràn àwọn ènìyàn Ukraine lọwọ”, Bob Rae sọ èyí.

Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti gbé mẹ̀wá lé lọ́gọ̀rún bílíọ̀nù dọ́là kalẹ̀ fún ìrànwọ́ ilẹ̀ Ukraine, bó-ti-lẹ̀-jẹ́pé ìbò dídì láti máa ṣe àtìlẹ́yìn lọ fún ilẹ̀ Ukraine àwọn ọmọ Amẹ́ríkà ti wálẹ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button