Take a fresh look at your lifestyle.

Àǹfààní láti kọ́wèé lọ́fẹ̀ẹ́: Àwọn ènìyàn méjìlé-láàdọ́rin ṣetán láti gbéra ní Nàìjíríà lọ sí Hungary

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 221

 Àwọn ọmọ Nàìjíríà méjìlé-láàdọ́rin ti wọn  fun ni Àǹfààní láti kọ́wèé lọ́fẹ̀ẹ́ ni orilẹ-ede Hungary lo ti ṣetán láti gbéra ní Nàìjíríà ni ọjọ kejile-logun, oṣu kẹsan an 2023.

Minisita ipinlẹ fun eto ẹkọ ni Naijiria, Dokita Yusuf Sununu sọ eyi nibi ayẹyẹ idagbere pẹlu awọn ti wọn jẹ anfaani naa, ni Abuja, olu ilu.

Sununu wa rọ awọn to janfaani naa lati jẹ aṣoju rere orilẹ-ede ki wọn o si jẹ eroja iyipada nigba ti wọn ba pada si orilẹ-ede.

O tun wa gba wọn niyanju lati tunbọ ṣafihan iwa rere ti wọn ti ni tẹlẹ, ki wọn o si kẹkọọ, tun ẹkọ kọ, ati ki wọn o tun maa kẹkọọ bi wọn ṣe bẹrẹ igbesẹ kinni ti irinajo wọn.

O yẹ ki a ṣe akiyesi pe oore Àǹfààní láti kọ́wèé lọ́fẹ̀ẹ́ jẹ ere fun iṣẹ to dara julọ ati pe o tun jẹ iwuri fun awọn ọmọ Naijiria to mọwe ti ko si lowo lati lọ kawe ni ilu okeere,” Sununu sọ bayii.

O tun wa gba wọn nimọran lati kọ iṣẹ ọwọ to ba wa ni Hungary ti wọn si le fi ranra wọn lọwọ, Naijiria ati gbogbo agbaye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button