Ẹgbẹ́ Ondo State Conscience Movement, OCM sọ pé àwọn yóò káàkiri Wọ́ọ̀dù Mẹ́tàleiúgba ní ìpínlẹ̀ Ondo láti ta àwọn ènìyàn jí nípa ìbò dídì àti ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀.
Alága ẹgbẹ́ náà, ọ̀gbẹ́ni Shalom Olaseni, ló sọ èyí ní ọjọ́ Ọjọ́rú pé ṣíṣe èyí yóò jẹ́ kí àwọn èniyàn kópa nínú ìbò tó ń bọ̀.
Olaseni sọ pé ṣíṣe èyí ni kíákíá jákèjádò ìpínlẹ̀ náà se pàtàkì nítorí pé àbájáde ìbò tó kọjá ti da omi tútù sí ọ̀pọ̀ èniyàn lọ́kàn láti dìbò lọ́jọ́ iwájú.
Ọ̀gbẹ́ni Olaseni sọ pé ní àkókò tí wọ́n bá ń lọ káàkiri yí, ẹgbẹ́ yóò súnmọ́ wọn pẹ̀kí pẹ́kí láti lè jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ́wọn yé wọn yékéyéké nípa lílo igberiko, awọn olórí àti alẹ́nulọ́rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan Wọ́ọ̀dù Mẹ́tàlélúgba.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply