Àwọn ọmọ ologun Joint Task Force Northwest Operation HADARIN DAJI lábẹ́ Ikọ̀ kẹjọ ọmọ ológun Nàìjíríà ti gba àwọn tó wà láhàámọ́ ajínigbé méjìdín-lógún sílẹ̀ ní agbègbè tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́, tí ó wà lábẹ́ Zamfara, Kebbi, Katsina àti ìpínlẹ̀ Sokoto ní sísẹ̀ńtẹ̀lé, ní Àríwá iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.
Alaye kan lati ọdọ oṣiṣẹ ologun fun eto ibaraẹnisọrọ ti Operation HADARIN DAJI, Ajagun Yahaya Ibrahim sọ pe aṣeyege ti wọn ṣe laipẹ yii waye latari dida awọn ọmọ ogun si Forward Operating Base (FOB) ní ijọba ibilẹ Anka ti ipinlẹ Zamfara.
Ikọ naa gba awọn ti wọn ji gbe marun un silẹ lẹyin ti awọn ati adigunjale naa yinbọn funra wọn ni opopona Anka – Baggega, ni ipinlẹ Zamfara. Awọn adigunjale naa fipa mu awọn olufaragba naa nigba ti wọn di ọna Anka – Baggega ti wọn si ji ọpọlọpọ eniyan ti o wa ninu ọkọ ti o n ko ohun tita lọ si ọja ni ijọba ibilẹ Anka.
Bakannna, Awọn ọmọ ologun ti Forward Operating Base Hannutara ní ipinlẹ Zamfara, ti gba awọn afaragba meji ti wọn ji gbe ninu oko wọn. Awọn ajinigbe fi wọn silẹ nigba ti wọn ri pe awọn ọmọ ogun n bọ fun iwolẹwo kaakiri ti wọn maa n ṣe si ibi to sunmọ oko naa.
Leave a Reply