Ìjọba Nàìjíríà ti sọ pé òun ti ṣetán láti tẹramọ́ akitiyan lórí ìdìdese àánú ọmọniyan jákèjádò orílẹ̀-èdè.
Eleyii waye bi Naijiria se darapọ mọ agbegbe lagbaaye lati ṣajọyọ ayajọ inu rere.
Nibi irin loju opopona lati sami ọjọ naa, ile-iṣẹ ijọba to n mojuto eto iṣeaanu, iṣakoso ajalu, ati idagbasoke ibaraẹniṣepọ lawujọ, sọ pe; “Naijiria ati awọn agbegbe to n ṣaanu ti gbaradi lati dide iranlọwọ lasiko ipeninija Kankan.”

Akọwe agba ti ile iṣẹ ijọba naa, Dokita Nasir Sani-Gwarzo, ti o ṣe adari irin loju opopona naa, fidiẹ mulẹ pe aimọye eniyan lo n wa aanu jakejado Naijiria lori awọn ipenionija, latori laasigbo ati idigunjale si ifigagbaga laarin awọn agbẹ ati adaran pẹlu ipa iyipada oju ọjọ.
Pẹlu awọn ipeninija naa, Sani-Gwarzo sọ pe iranlọwọ aanu yoo maa wa larọwọto gbogbo awọn to ba nilo rẹ.
Leave a Reply