Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Kí Babangida Kú Oríire Ọjọ́ Ìbí Ọdún Méjìlélọ́gọ̀rin Ní Òkè Eèpẹ̀

0 213

 

Ààrẹ Bọla Tinubu yayọ̀ pẹ̀lú ebí, ọ̀rẹ́ àti ẹgbẹ́ ọ̀gágun Ibrahim Badamasi Babangida (Rtd), bi ààrẹ ológun orílẹ̀-èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí se pé méjìlélọ́gọ̀rin ní ọjọ́ ọjọ́bọ̀, kẹtàdínlógún, oṣù kẹjọ, ọdún 2023.

 

Ààrẹ Tinubu Kí ààrẹ ológun tẹ́lẹ̀ rí kú oríire, ẹni tó ti ṣe iṣẹ́ ológun ní àseyè títí dé ipò ọ̀gá pátápátá tí ó sì ti sin orílẹ̀-èdè yìí dáradára pàápàá jù ní àkókò ogun abẹ́lé tí iṣẹ́ rere rẹ̀ kò leè parẹ́ láíláí.
Iṣẹ́ rere bíi: ìdásílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀, ilé ìṣẹ́ tí a lè fojú rí, ìtẹ̀síwájú ní ti ẹ̀ka ilé iṣyẹ ìròyìn, ètò ìlera, ààbò abbl..

 

Ààrẹ Tinubu mọ rírì ipò asájú orílẹ̀-èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí lẹ́yìn tó ti fẹ̀yìntì ní nǹkan bi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, ó sì tún ń lo ọgbọ́n rẹ̀ láti gba àwọn olóṣèlú ní ìmọ̀ràn ní ilẹ̀ yìí àti ni òkè òkun.

 

Ààrẹ wá gbàdúrà fún ìtẹ̀síwájú ìlera pípé ọgágun Babangida àti ti àwọn ẹbí rẹ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button