Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Nàìjíríà Tí Fọwọ́sí Àwọn Ìwé-àṣẹ Àṣẹ Mẹ́rin Kàn

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 341

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí buwọ́lù àwọn ìwé-aṣẹ mẹ́rin ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀ tó ṣé fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ọjọ́ iburasipo rẹ̀

Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ lórí àwọn iṣẹ́ pàtàkì, Ibaraẹnisọrọ àtí Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Dele Alake ṣé àfihàn èyí làkókò tó n ṣàlàyé fún àwọn òníròyìn Ilé-iṣẹ́ ìjọba ní Ọjọ́bọ̀.

Alake ṣàlàyé àwọn ìwé-àṣẹ mẹ́rin náà:

“1. Òfin Ìṣúná (Ìyípadà Ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́) ìwé òfin náà tó yẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kàrún ùn ọdún yìí, ní wọ́n tí sùn síwájú sí ọjọ́ kínní oṣù kẹsán, ọdún 2023. Èyí yóò jẹ́ kí àtúnṣe òfin owó-orí múlẹ̀, ìyẹn National tax policy, 2023.

“2. Àwọn Aṣọ̀bodé, (Ìyípadà ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ owó-orí) Atunse 2023. Èyí náà tún tí gbá ọjọ́ tún. Dípò ọjọ́ kẹ́tadìnlọ́gbọ́n oṣù kẹ́ta ọdún 2023, yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kínní oṣù kẹjọ, ọdún 2023 ní ìlànà sí òfin owó-orí tí orílẹ̀-èdè yìí.

“3. Ààrẹ tí fọwọ́ sí dídádúró tí ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún owó-orí “Excise Tax” lórí ilé-iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti owó-orí “Excise Duty” tí àwọn ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ wà.

“4. Ní àfikún sí ẹ̀kà ìṣòwò, Ààrẹ tí pàṣẹ fún ìdádúró tí “Green Tax” túntún tá ṣé nípasẹ̀ “Excise Tax” lórí ike àti ìgò àwọn òún mímú. Ààrẹ tún tí pàṣẹ ìdádúró Owó-orí túntún lórí àwọn ọkọ àyọkẹlẹ kàn.”

O sọ síwájú sí wípé àwon iwé-àṣẹ náà wà látí ṣé àdínkù wàhálà àwọn ọmọ Nàìjíríà pàápàá jùlọ àwọn oníṣòwò.
Tún kà nípa:Ààrẹ Tinubu Dá Owó-Orí Dúró Lórí Àwọn Ilé-iṣẹ́ Ẹrọ Ìbánisọ́rọ́

O tún sọ pé Ààrẹ Tinubu tí pinnu láti ṣé àtúnyẹwò àwọn ẹdun ọkàn àwọn aráàlú lórí apọju owó-orí àtí àwọn òun idiwọ ìṣòwò.

Alake tún ṣàlàyé pé Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò tẹ̀síwájú látí fikunlukun pẹ̀lú àwọn aráàlú kí ó tó lé fí kún owó-orí èyíkéyìí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button