Wọ́n tún ti tún Alhaji Mohammed Lugerewo, tí ó jẹ́ adarí ilé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹfà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí yìí ní ipinlẹ Gombe, gẹ́gẹ́ bí adarí ilé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ẹ̀keje ní iịpínlẹ̀ náà.
Lugerewo, tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC),tí ń ṣojú Àringbùngbùn Akko, jáwé olúborí nígbà tí kò ní olùkojú lásìkò ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ ilé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ẹ̀keje,ní Ọjọ́ọ́rú, ní Gombe.
Alhaji Nasiru Abdulkarim ti ẹgbẹ APC, ẹni ti n ṣoju Ariwa Dukku, fa adari naa silẹ tí Alhaji Zubeiru Ayala, ti n ṣoju ila oorun Billiri East labẹ Asia People’s Democratic Party (PDP), si ṣikeji rẹ.
Sadam Bello ti APC, tí ń ṣojú Àríwá Funakaye, náà sì jáde bíi igbákejì adarí, láìní olùkojú.
Leave a Reply