Ẹgbẹ́ tí kìí ṣe tìjọba kan, Àjọ Ààfín ti rọ àwọn Ààfín láti yẹra fún òòrùn fún ààrùn jẹjẹrẹ àwọ̀. Àjọ náà sọ pé àwọn Ààfín máa ń ní ààrùn jẹjẹrẹ, tí òòrùn sí jẹ́ ewu tó burú jùlọ, tí ó le fa ààrùn jẹjẹrẹ.
Olùdásílẹ̀ àti Adarí Aláṣẹ Àjọ náà, Jake Epelle, sọ eléyìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ṣàyajọ̀ Ààfín káríayé ọdún 2023, pẹ̀lú àkọlé , ‘Agbára àjọṣepọ̀.’
Àjọyọ̀ àyájọ́ Ààfín káríayé máa ń wáyé ní gbogbo ọjọ́ kẹtàlá ọdọọdún, láti ṣàmì ẹ̀tọ́ àwọn Ààfín lágbàáyé.
Gẹgẹ bi Ajọ iṣọkan agbaye, akọle tọdun yii, “Agbára àjọṣepọ̀,” jade lara akọle ọdun to kọja tí ó jẹ́ ‘pẹlu iṣọkan wọn yoo gbọ tiwa’.
Leave a Reply