Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé iṣẹ́ rọ àwọn àgbẹ̀ láti ṣe àyẹ̀wò èrùpẹ̀ kí wọ́n tó lòó fọ́gbìn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 228

Ọ̀jọ̀gbọ́n Saminu Abdulrahman Ibrahim, Alákòóso ilé iṣẹ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Èrùpẹ̀ ní Nàìjíríà (NISS), ti Agbègbè Àrínwá Ilà oòrùn, ti rọ àwọn àgbẹ̀ láti ṣe àyẹ̀wò èrùpẹ̀ kí wọ́n tó lòó fọ́gbìn.

Ó sọ̀rọ̀ lórí ìgbélárugẹ ibùdó ìpèsè Ajílẹ̀ fún gbígbin ohun ọ̀gbìn ní Àrínwá Nàìjíríà lábẹ́ ètò Àkùrọ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, níbi ayẹyẹ àyájọ́ Green Field, ní agbègbè Warji àti Sakwa Zaki.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, “Àwọn àgbẹ̀ onírẹsì ní ìpínlẹ̀ Bauchi, ní ìjọba ìbílẹ̀ Warji àti Sakwa gbọ́dọ̀ rí iṣẹ́ àgbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ tí yóò kojú ìpọ́njú àti níní òmìnira.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button