“Kòsí ìbẹ̀rù lórí ilé-ìgbìmọ̀,” – Adarí ilé ìgbìmọ̀ tẹ́lẹ̀ rí
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Adarí ilé ìgbìmọ̀ tẹ́lẹ̀ rí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò, Sẹnetọ Ovie Omo-Agege, ti sọ pé kò séwu lórí ilé-ìgbìmọ̀ pẹ̀lú bí Sẹ́nétọ̀ Godswill Akpabio ṣe jẹ́ Adarí ilé ìgbìmọ̀ kẹwàá tuntun.
Ó sọ èyí nínú àlàyé oríire tí ọ̀gá àgbà Akọ̀wé rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Sunny Areh, fi síta tí ó sì pín fún àwọn akọ̀ròyìn,ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun,ní Asaba, olú ìlú ìpínlẹ̀ Delta.
Lásìkò saa meji Omo-Agege, (2015- 2019; 2019- 2023) gẹge bi igbakeji Adarí ilé ìgbìmọ̀, tí ó ṣoju Aringbungbun agbegbe Delta.
Ó ní oun ni igboya ninu “ iṣeto Akpabio”.
Omo-Agege, ti o jẹ oludije ipo gómìnà ìpínlẹ̀ Delta labẹ asia ẹgbẹ́ oṣelu APC ní ọjọ́ kejidin-logun,oṣu Ẹrèná, ọdún 2023, tún ṣajọyọ pẹlu Sẹnetọ Jubrin Barau, ẹni ti o jawe olubori fun igbakeji adarí ilé ìgbìmọ̀.
Leave a Reply