Ààrẹ Muhammadu Buhari tí kẹ́dùn lórí ìpàdánù ẹ̀mí méjì tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ America àti ọlọ́pàá Nàìjíríà méjì tí wọ́n tẹ̀lé wọ́n níbí ikọlù tí àwọn agbebọn kàn ṣé ní ìjọba ìbílẹ̀ Ogbaru ní Ìpínlẹ̀ Anambra.
“Inú mi bà jẹ́ gan-an nígbà tí mo gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe pa àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ìjọba náà àtàwọn ọlọ́pàá wa tí wọ́n ń tẹ̀ lé wọn, mó bá àwọn ìdílé tí wọ́n pá ọmọ wọ́n, Ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ America àti Ilé-iṣẹ́ ọlọpa Nàìjíríà, NPF kẹ́dùn iṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ yìí.
Bákannáà ní a tún sọ fún Ààrẹ Buhari nípa ìpànìyàn burúkú tó ṣẹ̀lẹ̀ ní àgbègbè Bwoi ní ìjọba ìbílẹ̀ Mangu ni ìpínlẹ̀ Plateau, àtí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará abúlé Adaka ni ìjọba ìbílẹ̀ Makurdi àti ní àgbègbè Ijaha ní ìjọba ìbílẹ̀ Apa ní ìpínlẹ̀ Benue.
Ààrẹ náà sọ pé inú rẹ̀ kó dún rárá látí àwọn iṣẹ̀lẹ̀ wọnyí, ó sí ránṣẹ ìtùnú tòótọ́ sí àwọn ìdílé tí pàdánù àwọn ọmọ wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ló ṣé ìlérí pé ọwọ́ yóò bá gbogbo wọ́n láìpẹ́.
Leave a Reply