Take a fresh look at your lifestyle.

PDP ṣèdárò ikú igbákejì alága gúsù iwọ̀ oòrùn lápapọ̀, Soji Adagunodo

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 225

Ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic, PDP, ti ṣèdárò ikú igbákejì alaga gúsù iwọ̀ oòrùn lápapọ̀,tí ó tún figba kan jẹ́ alaga fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Aṣofin Soji Adagunodo.

Àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé ètò ìpolongo lápapọ̀, Debo Ologunagba fi síta,kéde ikú rẹ̀,tí ó sí tún ṣàpèjúwe Aṣòfin Adagunodo gẹ́gẹ́ bíí adarí tó nígboyà,ìfọkànsí, tí kò sì níbẹ̀rù,olùgbọ́ ti gbogbo ènìyàn ní tòótọ́,ọlọgbọ́n aṣòfin,olùṣàkóso tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan àti alápèjọ ní ìgbèríko, tí ó fi gbogbo nǹkan tó ní,ọpọlọ,àti agbára rẹ̀ wá dáradára fún àwọn ènìyaǹ nípasẹ̀ PDP.

Ologunagba sọ pé Adagunodo jẹ́ ajàjàgbara akẹ́kọ̀ọ́,ó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún ìgbà méjì,Kọmíṣọ́nà ti ìpínlẹ̀ fún Àṣà àti àbẹ̀wò afẹ́,alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP,lẹ́yìnnáà, tí ó tún jẹ́ igbákejì alága àpapọ̀ ti gúsù iwọ̀ oòrùn,tí ó tawọ́n yọ ní gbogbo ọ̀nà , gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣèlú tí kò wọ́pọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button