Take a fresh look at your lifestyle.

Àkójọpọ̀ Èsì Ìbò Ti Bẹ̀rẹ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Méjìdílnọ́gbọ̀n- Àjọ Elétò Ìdìbò

0 207

Àjọ elétò ìdìbò ti fi ọ̀rọ̀ léde pé àkójọpọ̀ èsì ìdìbò jákè-jádò ìpínlẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n ti bẹ̀rẹ̀, fún ìkẹ́sẹjárí ètò náà lójúnà àti kéde àwọn tí ó jáwé olúborí.

Àrídájú wà pé ètò ìdìbò Gómìnà ti ọjọ́ Àbámẹ́ta kò wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́jọ̀ : Anambra, Bayelsa, Edo, Ekiti, Imo, Kogi, Ọsun, àti Ondo.

Àjọ náà fi léde pé, ìsàkójọpọ̀ èsì ìdìbò Ìpínlẹ̀ Èkó yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú (Sunday) ní déédé agogo mọ́kànlá òwúrò, nítorí pé èsì ìbò kò tètè dé gbòngàn àkójọpọ̀ ìbò láti àwọn ìjọba ìbílẹ̀.

Bákan náà ni Ọ̀gbẹ́ni Niyi Ijalaye, ẹni tí ó jẹ́ alákòsóo ti ìpínlẹ̀ Ògùn fi léde nípa sísún ètò náà síwájú di ọjọ́ Àìkú àti ojúgbà rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà se ìfiléde sísún ìtẹ̀síwájú àkójọpọ̀ èsì ìdìbò di ọjọ́ Àìkú.

Lákòtán-án, ìrètí wà pé lẹ́yìn ìsàkójọpọ̀ àwọn èsì ìdìbò, ìkéde àwọn tí ó jáwé olúborí yóò wáyé jákè-jádò Ìpínlẹ̀ méjìdílọ́gbọ̀n tí ìdìbò náà ti wáyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button