Ikọ̀ Remo Stars ti yan Usman Abd’Allah gẹ́gẹ́ bí Akọ́nimọ̀ọ́gbá , àjọ ti Nigeria Premier Football League (NPFL) lo èyí.

Abd’Allah ti ṣe àkóso àwọn ẹgbẹ́ bọ́ọ̀lù jákèjádò Asia àti France. Ní Nàìjíríà, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ olùkọ́ni Super Eagles lábẹ́ idari Jose Peseiro.
Òun ni Akọ́nimọ̀ọ́gbá fún Enyimba FC. Lábẹ́ ìtọ́nisọ́nà rẹ̀, Enyimba dé ìpele to kángun sí àsekágbá ìdíje CAF Confederation Cup. Ó tún ṣe amọ̀nà Enyimba sí àmì-ẹ̀yẹ ti wọn fi gb’ade idije NPFL ní àsìkò odun 2018/2019.
Abd’Allah ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí ti yóò rán lọwọ, lẹ́yìn tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí UEFA Pro License, ó tún ní àwọn oyè gíga nínú ìkọ́ni bọ́ọ̀lù àti ìṣàkóso ẹgbẹ́ láti Le CREPS de Montpellier, France.
Ó ní Ìpele kínní ti Ìmọ̀ràn Ìkọ́ni Ìdánimọ̀ (NCAP) láti orílẹ-èdè Singapore àti Ìwé Ẹ̀rí Ìkọ́ni LaLiga tí ó gbajúmọ̀.
Ikọ̀ Remo ń jà láti yẹra fún ìfàsẹ́yìn ní àsìkò yìí, lẹ́yìn tí wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ NPFL àkọ́kọ́ wọn ní àsìkò tó kọjá. Abd’Allah so ìriri rẹ̀ kárí ayé pọ̀ mọ́ ìmọ̀ íjinlẹ̀ nípa ere bọ́ọ̀lù Nàìjíríà, èyí tí ó mú kí ó wà ní ipò tó dára láti ran Remo Stars lọ́wọ́ láti dúró ní ipò kinní.

Iku Remọ, Ìràwọ̀ Sky Blue, tí wọ́n rapala wà ni ipò kọkandinlogun, yóò gbàlejò ikọ̀ Katsina United ní ìparí ọ̀sẹ̀ yìí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san