Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Arsenal Ń Gbìyànjú Láti Borí Ikọ̀ Chelsea

158

 

Ikọ̀ Arsenal ní afojusun láti sẹgun ikọ̀ Chelsea ti wọn bá koju ara won ní òpin ọsẹ yìí ní ọnà láti jékí ala wọn láti gbá ife ẹyẹ Liìgì wọn wà sì imusẹ.

Fun ikọ̀ Mikel Arteta, ise naa rọrun—lati gba ami meta (3) lati le jeki asiwaju won wa ni oke tabili Premier League tente.

Igba ikẹhin ti Arsenal ṣẹgun Chelsea ni igba mẹta ni akoko kanna tun jẹ igba ikẹhin ti wọn gba Premier League, ni 2003-2004. Ati pe botilẹjẹpe ọkan le ma ṣe pataki si ekeji, Arsenal n lọ fún ifagagbaga ní ọjọ Àiku ni ọnà láti sẹgun.

Ní ìparí ọ̀sẹ̀ tó kọjá, Ikọ̀ olori Arsenal padà bọ̀ sípò iwájú pẹ̀lú ìṣẹ́gun ayò merin sì oókan, (4-1) pẹlu ikọ̀ Tottenham Hotspur, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó kéré sí àmì mẹ́ta tí wọ́n n wá láti ọdọ Chelsea ní ọjọ́ Àìkú yóò fi wọ́n sínú ewu ikọ̀ City,

Chelsea tí ó wà ní ipò karùn-ún kò tí ì ṣẹ́gun ìkọ Arsenal láti ọdún 2021 wọ́n sì pàdánù ní ìgbà méjì nínú ìdíje League Cup ní ìpele to kangun sì àsekágbá wọn ní oṣù Knni sí oṣù Kejì, ṣùgbọ́n wọ́n ti gba omin pẹlu ikọ Arsenal ní oṣù Kọkànlá bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gba idije náà parí pẹ̀lú agbábọ́ọ̀lù mẹ́wàá.

Ní báyìí, ikọ̀ Manchester City ń lọ sílé ikọ̀ Leeds fún ifagagbaga, ẹni tí ó fẹ́rẹ̀ gba ọ̀mìn pẹlu wọn ìdíje ní oṣù Kọkànlá ọdún 2025.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button