Take a fresh look at your lifestyle.

Orile-ede Naijiria Wà Digbi Ní Ìbáṣepọ̀ Pẹlu Orílẹ-èdè Saudi Arabia– Minisita

74

 

Minisita fún Ìròyìn àti Ìtọ́sọ́nà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mohammed Idris ti tún sọ pé Nàìjíríà yóò ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Saudi Arabia ní gbígbé àlàáfíà àgbáyé lárugẹ, ìjíròrò láàárín àṣà, àti ètò itẹsiwaju tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé.

Minisita fún Ìròyìn sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí ó ń gba Aṣojú Ìjọba Saudi Arabia sí Nàìjíríà, Yosef Bin Mohammed Al Balawi, àti àwọn aṣojú rẹ̀ ní lalejo ọ́fíìsì rẹ̀ ní Abuja, Olu ilu Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, “Nàìjíríà yóò máa tẹ̀síwájú láti mú kí ìbáṣepọ̀ àárín gbùngbùn pẹ̀lú Ìjọba Saudi Arabia lágbára nípasẹ̀ ìbáṣepọ̀ tó pọ̀ sí i nínú ìròyìn, ìbánisọ̀rọ̀, ètò ọrọ̀ ajé, àti ààbò.”

Minisita ṣapejuwe ibẹwo naa gẹgẹbi igbesẹ pataki to faaye gba ifowosowopọ̀ to lọ́ọ̀rìn laarin awọn orilẹ-ede mejeeji.

O tẹnumọ pe Naijiria mọyì Ibasepọ̀ ọlọjọ́pipẹ́ ti o ti wa pẹlu ilẹ̀ Saudi Arabia ati pe o ti pinnu lati fa ifowosowopo kọja awọn apa ibi pataki kan gun.

Ó tún fi ìdúróṣinṣin Saudi Arabia hàn nipa sí ṣíṣe atilẹyin fún àwọn arìnrìn-àjò to ní lọ sí ilẹ mimo láti orílẹ-èdè ní Nàìjíríà, ó sì ṣípayá àwọn ìsapá tó ń lọ lọ́wọ́ láti mú kí ìbáṣepọ̀ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pọ̀ sí i tí yóò ṣe àǹfààní fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè méjèèjì.

Ìbẹ̀wò ọ̀lola náà ni a ti rí Akọ̀wé Àpapọ̀, Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn àti Ìtọ́sọ́nà Orílẹ̀-èdè yìí , Ogbodo Chinasa Nnam; Olùdarí, Ìbánisọ̀rọ̀ Gbogbogbò, Henshaw Ogubike; Olùdarí, ọgá agba, Public Relations and Protocol, Haruna Suleiman, PhD; Olùdarí, ọgá agba, National Archive, Dókítà Evelyn Odigboh; àti Olùdarí Gbogbogbò ilé iṣẹ Voice of Nigeria, Mallam Jibrin Baba-Ndace àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button