Àjọ Ilé-iṣẹ́ Transmission Company of Nigeria (TCN), nípasẹ̀ Agbègbè Benin rẹ̀, ti ṣe àtúnṣe láti mú àwọn ilé tàbí ohunkohun tó leè fa idiwọ kuro ninú ọ̀nà gbigbe Ẹ̀rọ tabi waya ina Ihovbor–Ajaokuta 330kV kúrò ní agbègbè Ihovbor, Ìpínlẹ̀ Edo, gúúsù Nàìjíríà.
Olùdarí Àgbà àjọ TCN, Public Affairs, Ndidi Mbah, ẹni tí ó ṣí èyí payá ní Abuja, olú-ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, sọ pé iṣẹ́ náà jẹ́ ara àwọn akitiyan láti dáàbò bo àwọn èroja ina pàtàkì àti láti rí i dájú pé ìgbékalẹ̀ iná mànàmáná kò dáwọ́ dúró.
Arábìnrin Mbah ṣàlàyé pé “akanse iṣẹ ọjọ́ méjì náà ni wọn ṣe láti gba ọ̀nà TCN (ROW)- Right of Way (ROW) padà ní ọ̀nà alakalẹ̀ rẹ̀”
Àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀, àwọn olórí ọ̀dọ́, àti àwọn alenulọ́rọ̀ pàtàkì mìíràn ni wón ti sọ fún kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe náà, èyí tí ó mú kí wọ́n ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìmúṣẹ ètò náà ní àlàáfíà.
Ìgbésẹ̀ náà ṣe pàtàkì láti dáàbò bo ẹ̀mí àti dúkìá, láti dènà ìdènà lilọ ọ̀pa ina tabi waya, àti láti pa àwọn ohun eelo dúkìá pàtàkì tí ó sopọ̀ mọ́ Ihovbor àti Ajaokuta mọ́.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san