Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Fa Ìfòfindè Koro Èso Òrí Lọ Sókè Òkun Sẹ́yìn

46

 

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ́ sí ìfàagùn ifofinde koro Eso Orí lọ sókè Okun sẹyìn fún ọdún kan sí i, láti ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì, ọdún 2026, sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kejì, ọdún 2027.

Ìfòfindè náà ní èrò láti mú kí agbára ìṣiṣẹ́ pọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti mú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn dara sí i ní àwọn agbègbè tí wọ́n ń ṣeto rẹ àti láti gbé ìdàgbàsókè àwọn ọjà tí a n gbe lọ sókè okun lárugẹ síi.

Ìròyìn kan latí Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ lórí Ìròyìn àti Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga, fi sílẹ̀ ní ọjọ́rú sọ pé; “ìpinnu náà tẹnu mọ́ ìdúróṣinṣin ìjọba láti mú ìdàgbàsókè ilé iṣẹ́ pọ̀ sí i, láti mú kí ìfikún iye owó ilé lágbára sí i, àti láti ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn èto ti Àjọ Ìrètí Tuntun.”

Ìjọba Nàìjíríà fẹ kí a máa fi àwọn èso naa ṣe ori tabi bota latọwọ́ dọ́wọ́ wa nítorí pé bota ń gba ìlọ́po mẹ́wàá sí ogún owó èso rọ̀bì náà jáde.

Ó ṣì dúró ṣinṣin sí àwọn ìlànà tó ń gbé ìdàgbàsókè gbogbogbòò lárugẹ, iṣẹ́ àgbékalẹ̀ ní àdúgbò, àti láti fi Nàìjíríà sí olùkópa nínú ìníyelórí iṣẹ́ àgbẹ̀ kárí ayé.

Láti mú àwọn èròngbà wọ̀nyí ṣẹ síwájú sí i, Ààrẹ Tinubu fún àwọn Mínísítà méjì ti Ilé Iṣẹ́ Àpapọ̀ ti Ilé Iṣẹ́, Ìṣòwò àti Ìdókòwò, àti Ẹ̀ka Ìṣọ̀kan Ààbò Oúnjẹ Ààrẹ, Presidential Food Security Coordination Unit (PFSCU),(PFSCU), láṣẹ láti ṣètò ìmúṣẹ ètò orílẹ̀-èdè yìí ti yóò mú kí ìṣètò ilé iṣẹ́, ìṣòwò, àti ìdókòwò pọ̀ sí i ní gbogbo agbègbè ìpèsè eso orí ti yóò ti niyi.

Ó tún fọwọ́ sí gbígba ìlànà ìtajà tí Nàìjíríà commodity Exchange (NCX) gbé kalẹ̀ àti yíyọ gbogbo ìyọ̀ǹda kúrò nínú àwọn ìyọ̀ǹda tí ó fún ni láàyè láti kó àwọn èso òrí aise jáde taara.

Ààrẹ pàṣẹ pé, gbogbo ìpèsè koro òrî aise, raw shea nuts, tí ó pọ̀ jù jáde ní a ní láti tà soke òkun nípasẹ̀ ìlànà àjọ NCX nìkan, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí a fọwọ́ sí.

Àwọn èso ori, Shea, àwọn èso tí ó ní epo láti inú igi shea tí ó wọ́pọ̀ ní agbegbe Savanna ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni ohun èlò tí a fi ṣe ori ero, tí a mọ̀ fún ìpara, ìdènà ìgbóná ara, àti àwọn ohun-ìṣe antioxidant rẹ̀. ori tí a yọ jáde jẹ́ èròjà pàtàkì nínú ohun ìpara fún awọ ara àti irun, àti nínú epo sísè tí a lè jẹ.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button