Sẹ́nétọ̀ Seriake Dickson, tó ń ṣojú fún ìwọ̀ oòrùn Bayelsa ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ti gba ẹ̀bùn ìtọ́sọ́nà tó dájú fún ipa ribiribi rẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti àwùjọ lápapọ̀.
Àjọṣepọ̀ àwọn àjọ Civil Society Organizations ní Nàìjíríà, àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba, lábẹ́ àjọ Centre for Credible Leadership and Citizens Awareness, lo fún Sẹ́nétọ̀ Dickson ní gbọ̀ngán National Assembly Complex ní ilu Abuja.
Ẹgbẹ́ náà ṣàpèjúwe Sẹ́nétọ̀ Dickson gẹ́gẹ́ bí ohùn fún àwọn aláìlóhùn, ẹni tó ti fihàn nígbà gbogbo pé atọ́nisọ́nà ododo ni óún, to fi hàn nípasẹ̀ ìtọ́nisọ́nà àti ìgboyà láti dáàbò bo àṣẹ àwọn ènìyàn.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó gba ẹ̀bùn náà, Sẹ́nétọ̀ Dickson sọ pé òun lo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn oun ti kò rọrùn láti ṣe ní Nàìjíríà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn sí ènìyàn àti sísìn Ọlọ́run.
‘Kò rọrùn ní orílẹ̀-èdè yìí láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òtítọ́ láàárín ìjọba gbogbogbòò, nínú àwùjọ tí gbogbo ènìyàn ti máa ń fi ìrísí kan náà ya àwòrán. Ó jẹ́ àyíká tó le láti ṣiṣẹ́ nínú àwùjọ tó kún fún ìpolongo, ìfipábáni, àti ìkọ̀kọ̀,” ó sọ èyí.
Nígbà tí ó lo nǹkan bí ogún ọdún nínú iṣẹ́ ìjọba ní ìpele ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ̀, Sẹ́nétọ̀ Dickson sọ pé ó ṣòro láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òtítọ́ ní Nàìjíríà.

“Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí, mo lè sọ láti inú ìrírí mi pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà olóòótọ́ wà. Àwọn ọmọ Nàìjíríà aláápọn àti olùfẹ́ orílẹ̀-èdè wà. Wọ́n lè kéré, ṣùgbọ́n wọ́n wà”
Kí a má gbagbe pé, Dickson ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà fún Ìdájọ́ àti Agbẹjọ́rò Àgbà ní Ìpínlẹ̀ Bayelsa lábẹ́ Gómìnà Goodluck Jonathan láàárín ọdún 2006 sí 2007.
Ó di ẹni tí wọ́n yàn sí Ilé Àwọn Aṣojú láti ṣojú fún Sagbama – Ekeremor Federal Constituency láti ọdún 2007 sí 2012, nígbà tí ó di Gómìnà Ìpínlẹ̀ Bayelsa ó sì ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́jọ kí ó tó dara pọ̀ mọ́ Sẹ́nẹ́tọ̀ ní ọdún 2020 láti ṣojú fún Ìwọ̀ Oòrùn Bayelsa
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san