Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Yan Tunji Disu Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀ga Ágbá Àwọn Ọlọ́pàá

21

 

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti yan Igbákejì Aṣojú Àgbà ti Ọlọ́pàá, Tunji Disu, gẹ́gẹ́ bíí fidihẹ ọgá agba àwọn Ọlọ́pàá ní wàrànsesà.

Ìgbésẹ̀ náà wá nítorí àwọn ìpèníjà ààbò tí ó ń dojúkọ orílẹ̀-èdè yìí lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti àwọn ìlànà òfin tó wà.

Ààrẹ, nínú ìkéde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Bayo Onanuga, fi hàn pé òun ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìrírí AIG Disu, ìmọ̀ iṣẹ́ àti agbára ìdarí tí a ti fi hàn yóò pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó dúró ṣinṣin àti tí ó ṣe pàtàkì fún Ọlọ́pàá orílẹ-èdè Nàìjíríà ní àkókò ti o se pàtàkì yìí.

Onanuga tún sọ pé, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Òfin Ọlọ́pàá, Ààrẹ Tinubu yóò pe ìpàdé ti Ìgbìmọ̀ Ọlọ́pàá Nàìjíríà láìpẹ́ láti gbé yíyàn AIG Disu gẹ́gẹ́ bí Ipò ọgá Àgbà ti awọn Ọlọ́pàá, lẹ́yìn náà ni a ó fi orúkọ rẹ̀ ránṣẹ́ sí ile igbimo aṣòfin fún ìfìdí múlẹ̀ yiyan rẹ̀.

Aare naa fi imoriri iṣẹ takuntakun ọpọlọpọ ọdun ti Ogbeni Egbetokun fi ṣiṣẹ sin Ẹgbẹ ọlọpa orilẹ-ede yìí han, o yin fun, ifarada, ati ifaramo iduroṣinṣin rẹ lati mu eto aabo orílẹ-èdè Nàìjíríà lagbara ṣii ni akoko rẹ.

Ogbeni Egbetokun, ti wọn yan ni Oṣu Kẹfa ọdun 2023, n ṣiṣẹ fun igba ọdun mẹrin ti wọn ṣeto lati pari ni Oṣu Kẹfa ọdun 2027, ni ibamu pẹlu awọn ipese ti atunṣe ti Ofin ọlọ́pàá

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

.

Comments are closed.

button