Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Ṣọ̀fọ̀ Ààrẹ ASUU Tẹ́lẹ̀rí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Jeyifo

127

 

Ààrẹ Bola Tinubu ti fi ìbànújẹ́ hàn lórí ikú ogbontarigi ọ̀mọ̀wé àti Ààrẹ tẹ́lẹ̀ ti Ẹgbẹ́ àwọn àjọ Academic Staff Union of Universities (ASUU), Ọmowé,Ọ̀jọ̀gbọ́n Emeritus Biodun Jeyifo.

Ààrẹ ṣàpèjúwe ògbóǹtarìgì Jeyifo gẹ́gẹ́ bí èèkàn pàtàkì ọlọ́gbọ́n tí ìgbésí ayé rẹ̀ kún fún àwárí ìmọ̀ àti itẹsiwaju ìyí ọmọ ènìyàn

Ààrẹ kí Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀mọ̀wé Academic Staff Union of Universities, Nigerian Academy of Letters, Wole Soyinka Centre for Investigative Journalism, àti àwọn agbègbè ẹ̀kọ́ ti Yunifásítì ti Ibadan àti Obafemi Awolowo University ku ara fẹ́rakù.

Ààrẹ Tinubu gbàdúrà fún ìsinmi ọkàn ọ̀mọ̀wé tó ti kú àti fún okun fún ìdílé rẹ̀, àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé kárí ayé tó ti ṣìn pẹ̀lú ọlá.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button