Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ Shettima gbóríyìn fún ipa ìpínlẹ̀ Imo lórí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

18

Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ti gbóríyìn fún ipa tí kòwọ́pọ̀ tí ì̀pí́nlẹ̀̀ Imo kó lórí ìdàgbàsókè òṣèlú, ọlọgbọ́n, àti ọrọ̀ ajé láti bíi ààdọ́ta ọdún sẹ́yìn, tí ó sì ń ṣàpèjúwe ìpínlẹ̀ náà bíi alájọṣepọ̀ pàtàkì nínú ìdàgbàsókè orílè-èdè. Nigba ti o n sọrọ ni ọjọ Abameta lasiko ayẹyẹ aadọta ọdun ti wọn da ipinlẹ Imo silẹ, Igbakeji aarẹ Shettima wa jẹ iṣẹ Aarẹ Bola Tinubu, ti o si je ki ipinlẹ naa mọ ipa pataki ti o ko ninu idagbasoke orilẹ-ede.
O wa gboriyin fun adari oṣelu ipinlẹ naa, aṣeyọri ọlọgbọn, ẹbun apilẹṣe, ati okun eto ọgbin, paapaa julọ ninu epo pupa ṣiṣe, ti o si pe akiyesi si pe ipinlẹ Gusu iwọ oorun ti fi gbogbo igba jẹ aridunnu fun Naijiria.
Igbakeji Aarẹ diidii yọ Gomina Hope Uzodimma, sọtọ ti o si ṣapejuwe rẹ bii alatunṣe pataki ninu itan oṣelu ode onii Imo, ti o da ibawi pada, ilana, ati afidi mulẹ awọn ile iṣẹ lati ṣakoso wọn.
Igbakeji Aarẹ Shettima wa ni iṣesilẹ rere yii wa lati bi iṣejọba Dokita Kingsley Mbadiwe, ti “ iwuri imọrọsọ rẹ ranni leti oṣelu Naijiria,” Mbakwe, Gomina Alalubarika, ati Rochas Okorocha, ti o ṣapejuwe rẹ bii ọkan gboogi ọmọ Naijiria ti o ṣe iṣẹ iṣaanu fun ọmọ niyan pẹlu awọn ọmọ alailobii jakejado orilẹ-ede.
O tun ka ipa ọgbọn ati aṣa silẹ, paapaa julọ nipasẹ Oloye Flora Nwapa, “iya iwe kikọ ti Afirika tode oni,” ti o fun Awọn obinrin Afirika“ni ohun ikọwe ni igba ti wọn ko ro pe wọn le sọrọ.”
Igbakeji Aarẹ tun wa ṣajọyọ pẹlu ipa Imo ninu Nollywood nipasẹ awọn oṣere bii Genevieve Nnaji, Rita Dominic, ati Kanayo O. Kanayo, ati akọrin Onyeka Onwenu.

Comments are closed.

button