Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú Adarí Ìṣọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

22

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gbàlejò Adarí Ìṣọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ (AFRICOM), Ajagun Dagvin Anderson, ní ọjọ́ Aiku ní ilé isẹ́ orílẹ-èdè, Abuja.
Àwọn ti o wà nijokoo nibi ipade naa ni Oludamọran lori ọrọ aabo lorilẹ-ede, Nuhu Ribadu, Minisita fun ọrọ idaabobo, Ajagun fẹyinti Christopher Musa, awọn adari ile iṣẹ lorilẹ-ede, awọn olujiṣẹ AFRICOM, ati ile iṣẹ to n risi ọrọ ọrilẹ-ede Amẹrika ni Naijiria, Keith Heffern.
Awọn to tun wa nibẹ ni awọn oludari eto aabo ni Naijiria ati oluṣoju fun eto idaabobo ni orilẹ-ede Amẹrika fun ijiroro, gẹgẹ bi apa kan agbekalẹ ti n lọ lọwọ laarin Naijiria ati Amẹrika.
Nibayii, Amẹrika ti fidi rẹ mulẹ pe oun ti ko awọn ikọ kerejẹ awọn ọmọ ologun wa si Naijiria lara inawọ ifọwọsowọpọ aabo laarin Naijiria ati Amẹrika.
Ajagun Dagvin R.M. Anderson, ti o jẹ Adarí Ìṣọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ (AFRICOM), ni o ṣalaye igbesẹ yi ti o jẹ ijiroro ifidimulẹ ati ikoju awọn onijagidijagan ati idaabobo.

Comments are closed.

button