Take a fresh look at your lifestyle.

Adarí alátakò South Africa sún sẹ́gbẹ̀ẹ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

11

Adarí Democratic Alliance (DA), John Steenhuisen ti kéde pé òun kò ní díje ìbò fún ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ lápapọ̀ ní oṣú kẹrin, ìpinnu tó fa ìṣiyèméjì sí ìṣọ̀kan ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè (GNU).
Steenhuisen, to ti ṣadari DA lati 2019, ti o si jẹ Minisita fun eto Ọgbin lọwọ lọwọ bayii, sọ pe oun yoo lo asiko oun to ku lori oye lati koju ajakalẹ aarun to burujai foot and mouth.
DA darapọ mọ GNU leyin ti ANC jakulẹ ni ile igbimọ to pọju lọ, ninu idibo gbogbogboo ọdun 2024, ti o mu ki ẹgbẹ to n ṣejọba lọjọ topẹ julọ l’Afirika lorilẹ-ede lapapọ ati alatako rẹ latilẹwa airotẹlẹ darapọ.
Ipa DA ṣe pataki si imuduro GNU ti idagbere Steenhuisen si fa ibeere pe kinni ọna ọjọ iwaju ati ifisọkan rẹ si iṣeto ijọba.
Steenhuisen, to jẹ ọmọ ọdun mọkandin-laadọta, bẹrẹ iṣẹ oṣelu rẹ ni gbati o wa ni ọdun mejile-logun ti o jẹ Kansilọ ni Durban fun ẹgbẹ Democratic Party, eyi ti o wa lẹyin DA.
O ni igbega latibi ipo yii ti o si di adari agbegbe KwaZulu Natal, lẹyin yi ni o di adari ile igbimọ ti o si wa tun di Adari ẹgbẹ lapapọ.
Lasiko rẹ, DA di ipo rẹ mu bii ẹgbẹ keji to tobi julọ ni orilẹ-ede South Africa ti o si gbori wọ ijọba apapọ fun igba alakọkọ.

Comments are closed.

button