Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kéde wí pé òun kò ní fi ààyè sílẹ̀ kí ẹnikẹ́ni tẹ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP (People’s Democratic Party) mọ́lẹ̀, fun ẹgbẹ́ míràn láti wà lórí ipò àṣẹ.
Makinde ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ lásìkò tó n ṣí ilé ẹgbẹ́ tuntun tó kọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, eléyìí tí wọ́n fi sọ orúkọ ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ alága Ìpínlẹ̀ fún ẹgbẹ́ náà, Olóyè Omokunmi Mustapha, fún ìṣàkóso àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Ilé ègbé tuntun ti Gómìnà fí fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP náà ló wà ní agbègbè Oke-Ado ni ìlú Ìbàdàn tii ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tí wọ́n ṣe fi orúkọ Sekiritariati tuntun náà sọ orí Olóyè Mustapha, Gomina Makinde sọ pé alága àtijọ́ náà kó ipa ribiribi nínú bí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe padà wá sípò àṣẹ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún 2019.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde láti ọwọ́ ẹni tii ṣe Olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀mọ̀wé Sulaimon Olanrewaju ṣe mú wá sí ìrántí pé Gomina Makinde kọ́ ilé ẹgbẹ́ kan bi èyí fún Ẹkùn Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni ọdún 2024, láti bù ọlá fún ẹni tó jẹ́ igbákejì Alága àpapọ̀ ẹgbẹ náà fún Ẹkùn Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn, olóògbé Sọji Adagunodo.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ náà èyí tí Alága Àpapọ̀ Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Àgbà (NWC) ẹgbẹ òṣèlú PDP, Alhaji Kabiru Tanimu Turaki léwájú rẹ̀ àti àwọn ọmọ Ìgbìmọ̀ Alábòójútó Ẹgbẹ́ (Board of Trustees) wà, Gómìnà Makinde tẹnu mọ́ ọ pé àwọn ènìyàn kan tí wọ́n lo àǹfààní ìpàdánù ẹgbẹ́ òṣèlú náà nínú ìdìbò ọdún 2015 láti jẹ gàba lórí ẹgbẹ́ náà kò ní ri ààyè láti tẹ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọ́lẹ̀ mọ́.
Nínú àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọn, Aya Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nigba kan rí, to tun jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ Ìgbìmọ̀ Alábòójútó PDP, Oloye Mutiat Ladoja; Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀ rí, Aṣòfin Monsurat Sunmonu; Ìgbákejì Alága Àpapọ̀ fún Ẹkùn Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn, Alhaji Kamorudeen Ajisafe; àti Alága Ìgbìmọ̀ Àgbààgbà ẹgbẹ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Saka Balogun, fi àsìkò náà dúpẹ́ lọwọ́ Gómìnà Makinde fún ọrẹ ilé ẹgbẹ́ tuntun náà àti fún ìdúró ṣinṣin rẹ̀ láì ka gbogbo ìpèníjà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà sí.
Wọ́n wá fi dá gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ PDP lójú pé ẹgbẹ́ òṣèlú náà yóò yege nínú ètò ìdìbò eléyìí tí yóò wáyé ni ọdún 2027, nígbà tó fi àsìkò náà rọ̀ wọ́n láti túbọ̀ máa ran ìṣèjọba Gómìnà Makinde lọ́wọ́ ki wọn sì dúró ṣinṣin nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láì yẹsẹ̀.
Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Alága fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Dayọ Ogungbenro ti sọ́ di mímọ̀ fún àwọn tó péjú pé ilé ẹgbẹ́ tuntun tí Gómìnà kọ́ náà ló n ṣe àpèjúwe irú adarí tí Gómìnà Makinde n ṣe.
Ogungbenro wá tẹnu mọ́ pé Gómìnà ti ṣe dáradára fún àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, pẹlú àwọn iṣẹ́ àkànṣe eléyìí tó farahàn, O wá rọ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ náà láti sán padà nípa dídi ìbò wọn fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ìdìbò ọdún tó n bọ.
Abiola Olowe
Ìbàdàn